Oro maree kegbe yewo - oro mare o kegbe yewo
Oro maree kegbe yewo - oro mare o kegbe yewo
Iberu oluwa ni ipinlese ogbon
Idajo ododo nii gb'orile-ede leke
Iwa otito pelu ife ni nfunni nigboya
Ni nmule toro ni mawujo toro
Ni nso orile-ede dalagbara
Oro mare kegbe yewo , omo yoruba
Oro mare o kegbe yewo
Sebi ogbon ologbon ni kiije ka pagba ni were
Omode gbon , agba gbon, lafi da'le ife
Taba s'oko oro s'ologbon eniyan, ofurufu ni yoti gbamu, o daju
Oro mare kegbe yewo
Oro mare o kegbe yewo
Oro sunnukun , oju sunnukun lafi nwoo
Enito jinsi koto, o ye kawon yoku 'o fi kogbon
Sugbon aja toma sonu konii gbo fere olode
Olukuluku eniyan lo ndaba ola
A ndaba odun kan, a ndaba odun mewa, koda, ogun odun tabi jubee lo
Sugbon eniti ku maapa, koniigbo girigiri ese
Eni t'Olorun fee mu , oniye osi ni gbariwo
Oro mare o tewe tagba, omo oodua nile loko
Oro mare o kegbe yewo
Awon taape wa jeun , tan muni lowo dani nko
Agbara 'o loun 'o wole, se bonile nio niigba
Kaka ki kiniun sakapo f'ekun, kolode o fotooto rode
Eniti kiki e ko yoni, aikini re kolee pani lebi
Adiye yogun o pogun, won ladiye o pomo re
Won gbadiye ta, won fowo e ra pepeye
Pepeye yogbon o pogbon, won tunni pepeye o pomo re
Won fi binu gbe pepeye ta won fowo e reyele
Eyele yeyin meji pere, o tun fi pakan soso
Keyele to pakan soso oun , seni won tepepe fun
Eyele lowa pomo re tab'adiye, e so fun wa
Oro mare kegbe yewo , omo Yoruba
Oro mare o kegbe yewo
Egbinrin ote , baati pakan , nikan nru
Iduro kosi , ibere kosi , feni to gbodo mi
Bawo lomo Oba yose wa daru , tomo ijoye yoose wa diwofa
Seboko kiije tibaba at'omo koma laala
Eyin asaju wa at'eyin igbimo lobaloba
Nibo lade duro, nibo gan lan lo
Aimete aimero, lomo iya mefa fi n ku soko egbaafa
Tabafe jagun molu, anilati fimosokan
Kokoro ti njefo, ara efo lowa
Sugbon bi'ro baa lo logun odun, ojo kan lotito o ba
E bawa kilo fawon atori-owo-baluje
Karanti pe , ile labo simi oko
Oro mare kegbe yewo, omo kaaro-oojiire
Oro mare o kegbe yewo