Baba pa laşe lat'Ọrun wa
Ki gbogbo aiye si wariri
Fun 'Jọ Mimọ, lat'Ọrun wa
Ijọ yi ni, yio wẹ aiye mọ
Ajẹ oşo, yio wariri
L'abẹ agbara Mimọ yi
Awọn Angẹli si kun f'ayọ
Iyanu, f'ọkọ ikẹhin
Halleluyah fun işẹ Oluwa
Igba ikẹhin na ti de
Kristi Jesu yio pada wa
Lati wa şe 'dajọ aiye
Iku Rẹ lori agbelebu
Ẹjẹ ati omi to nşan
Kuro ninu iha Mimọ Rẹ
Ko gbọdọ lo sori asan
Gbogbo oju yio si tun ri
Pẹlu awọn Angẹli Mimọ Rẹ
Kẹlẹşẹ ronupiwada
F'ọjọ iwariri nla na
Awọn Angẹli yio fun ipe
A o ka ilẹ at'Ọrun
Okun yio d'ohun airi mọ
Awọn oku yio ji dide
Imiran pẹlu ayọ nla
Imiran pẹlu ijiya
Elẹşẹ yio wariri lọjọ na
Awọn 'toku f'ọrọ Kristi
Awọn t'o ru Agbelebu Rẹ
Nwọn yio ji pẹlu ogo nla
A o wọ wọn laşọ ogo,
A ode wọn lade wura,
Mariwo ọpẹ lọwọ wọn,
Nwọn yio fo pade Kristi,
Arẹ ki yio si fun wọn mọ,
Halleluyah l'ohun orin wọn
Halleluyah oo oooh
Halleluyah l'ohun orin wọn
Halleluyah l'ohun orin wọn