Ìbà ooo Olódùmarè!
Ọba atẹ́nílẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ forí ṣagbeji omi O
Olódùmarè ló dá ayé
Olódùmarè ló dá Ọ̀run
Olódùmarè un là wá ń ṣìn
Àwọn irúnmọlẹ̀ gbogbo l'òjíṣẹ́
Ìṣẹ̀se un l'ẹ̀ṣìn àwa
Ìṣẹ̀se l'àdáyé bá
Ìṣẹ̀se l'àdáyé se
Ìṣèse e kò gbọ́dọ̀ parun
Ìṣẹ̀se
Ìṣẹ̀se O
Ìṣẹ̀se ìṣẹ̀se l'ẹ̀ṣìn àwa
Ìṣẹ̀se kò gbọ́dọ̀ parun
Olódùmarè ló dá ayé
Olódùmarè ló dá Ọ̀run
Olódùmarè ìwọ là wa ń ṣìn
Àwọn irúnmọlẹ̀ gbogbo l'ójíṣẹ́
Ìṣẹ̀se l'ẹ̀ṣìn àwa
Ìṣẹ̀se e l'àdáyé bá
Ìṣẹ̀se l'àdáyé se
Ìṣẹ̀se kò gbọ́dọ̀ parun
Ìṣẹ̀se e kò gbọ́dọ̀ parun
Ifá l'àbá o
Òrìṣà lọṣìn
Olódùmarè nìkan l'Ọba àjíwárífún láyé lọ́run
T'ọmọdé t'àgbà O ẹ wá f'oríbalẹ̀ fún Ọlọ́run Ọba
Ọba àjíkí Olódùmarè Ọba àjígẹ̀
Ọ̀gẹ̀gẹ́ Ọba tó gbé ilé aiyé ró o
Òkìkibìrí ají p'ọjọ́ ikú dà
Ọba atẹ́ní lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ forí ṣapeji omi o
Mo wárí fún Olódùmarè Ọba ìṣẹ̀se
Ìṣẹ̀se ìṣẹ̀se ìṣẹ̀se l'ẹ̀ṣìn àwa
Ìṣẹ̀se kò gbọ́dọ̀ parun
Ẹ ká re'lé ifá ooo
Ògúndá aláré
Wọ́n ní ọdún ọdún ni ni wọ́n pìṣán orí
È̩ẹ̀mí wọn a pàjùbà pọn'dò
Tó bá di ọdún mẹ́ta òní wọn a r'oko débi ìrókò agúnregejégé
Ẹni tí ó bá nijẹ òrúkọ (òbúkọ) píníṣín alẹ́ ànọ́
Ni yóò ò bá ni jẹ àgbò wààkàwaaka tó pé ọdún mẹ́ta
A d'ífá fún ìṣẹ̀se tí ń se olórí orò l'áyé
A bù fún ìṣẹ̀se tí ńse olórí orò iwà'run
Ifá ní baba ẹni ìṣẹ̀se ẹni ni o
Ìyá ẹni ìṣẹ̀se ẹni ni
Orí ẹni ìṣẹ̀se ẹni ni
Ifá ẹni ìṣẹ̀se ẹni ni
Èwo wá ni Olódùmarè fi fún ni tí ò tó ká mójú tó?
Ìṣẹ̀se ò sé kó danù o
Ẹ má fi ìṣẹ̀se tàfàlà
Ìṣẹ̀se ìṣẹ̀se ìṣẹ̀se l'ẹ̀ṣìn àwa
Ìṣèse kò gbọ́dọ̀ parun
Ẹ yé tàbùkù ìṣẹ̀se
Ìṣẹ̀se kìí se àsìse
Àdáyébá ọmọ nì ìṣẹ̀se ọmọ
Àdáyése ọmọ ni ìṣẹ̀se ọmọ o
Ifá ọ̀rúnmìlà ló ní òkún ṣú nàre-nàre
Ọ̀ṣà ṣú lẹ̀gbẹ lẹ̀gbẹ
Alásánraṣán àláṣànraṣàn
Omi orí ata
Èké ni má mọ ìgbẹ̀hìn ọ̀rọ̀
Óri pé ò sunwọ̀n ó fi irun kíká dá imú
Ó fi ìrùngbọ̀n dí àpinpin
A d'ífá fún ìṣẹ̀se èyítí ń se olórí orò láyé
Tí ń se olórí orò niwàrun
Ìyá ẹni ìṣẹ̀se ẹni ni
Baba ẹni ìṣẹ̀se ẹni
Orí ẹni ìṣẹ̀se ẹni
Ikin ẹni ìṣẹ̀se ẹni
Àdùnní af'omi ṣ'ọrọ̀ mo ní kí là ó bọ n'ifẹ̀ ká tó se awo o ?
Ìṣẹ̀se ni baba ètùtù
Ìṣẹ̀se là ó bọ n'ifẹ̀ ká tó se awo
Kí la ba bọ n'ifẹ̀ ká tó se awo o?
Ìṣẹ̀se ni baba ètùtù
Ìṣẹ̀se là ó bọ n'ifẹ̀ ká tó se awo
Kíni baba ètùtù?
Ìṣẹ̀se
Kíni orì ẹni?
Ìṣẹ̀se
Kíni ikin ẹni o?
Ìṣẹ̀se
Bàbá ẹni ńkọ́?
Ìṣẹ̀se e
Ìyá ẹni o?
Ìṣẹ̀se
Kí là bá bọ n'ifẹ̀ ká tó se awo o?
Ìṣẹ̀se ni baba ètùtù
Ìṣẹ̀se là ó bọ ni ifẹ̀ ká tó se awo